Jump to content

Emmanuel TV

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Emmanuel TV jẹ́ nẹ́tíwọkì tẹlifísàn Onígbàgbọ́ pẹ̀lú olú ile ní ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. T. B. Joshua ni Olùdásílẹ̀ rẹ̀, òun ni olùṣọ́-àgùntàn àgbà àtijọ́ ti Synagogue, Church of All Nations (SCOAN), ní ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Ó' tún jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀rọ ayélujára iṣẹ́-ìránṣẹ́ Kìrìtẹ́nì tí ó ṣe alábàápín jùlọ lóri YouTube ní káríayé pẹ̀lú àwọn alábàápín tí ó ju ọ̀kẹ́ kan lọ, ní Oṣù Kínní ọdún 2019. [1]

Ní ìparí àwọn ọdún 1990, SCOAN bẹ̀rẹ̀ gbígba àkíyèsí àgbáyé látara pínpín àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò, tí ń ṣàfihàn àwọn àgékúrú iṣẹ́-ìránṣẹ́ àkọ́kọ́ ti Joshua àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a sọ. Ní àfíkún si i,Joshua bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìtọlẹ́sẹẹsẹ ìgbà gbogbo jáde tí wọ́n sọ pé ó ń fi àwọn iṣẹ́ ìyanu hàn lóri ẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Bruce, James (2015-04-15). "Skewed Stats". https://www.worldmag.com/2015/04/skewed_stats.