Stefania Turkewich
Stefania Turkewich-Lukianovych | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Stefania Turkewich April 25, 1898 Lviv, Yukréìn |
Aláìsí | April 8, 1977 Cambridge, Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì |
Ẹ̀kọ́ | University of Lviv, Lviv Conservatory, Berlin Conservatory |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 1920's–1970's |
Stefania Turkewich-Lukianovych (tí a bí ní ọjọ́ karún-úndínlọ́gbọ̀n, oṣụ̀ kẹrin, ọdún 1898 tí ó sì di olóògbé ní ọjọ́ kejọ, oṣù kẹrin, ọdún 1977) jẹ́ atorinjọ, atẹdùru, àti onímọ̀-orin ọmọ orílè-èdè Ukraine, tí wọ́n dámọ̀ gẹ́gẹ́ bíi obìnrin atorinjọ àkọ́kọ́ ní Ukraine.[1] Àwọn Soviet ní Ukraine gbẹ́sẹ̀lé iṣẹ́ rè.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Stefania sí ìlú Lviv, ní orílẹ̀-èdè Austria-Hungary. Bàba-bàbá rẹ̀ (Lev Turkevich), àti bábà rẹ̀ (Ivan Turkevich) jẹ́ àlùfáà. Ìyá rẹ̀ Kormoshiv (Кормошів) máa ń tẹ dùrù, ó sì kàwé pẹ̀lú Karol Mikuli àti Vilém Kurz, ó sì tẹ dùrù pọ̀ pẹ̀lú Solomiya Krushelnytska.[2] Gbogbo wọn nínú ebí rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí orin, wọ́n sì ní ohun èlò orin kan tí wọ́n ń lù. Stefania máa ń tẹ pianó, dùrù, àti hàmóníọ̀mù.
Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Stefania bẹ̀rẹ̀ sí ní kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin kíkọ pẹ̀lú Vasyl Barvinsky. Láti ọdún 1914 wọ ọdún 1916, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Vienna pẹ̀lú Vilém Kurz. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní, ó kékọ̀ọ́ pèlú Adolf Chybiński ní University of Lviv, ó sì darapọ̀ mọ́ èkọ́ rè ní Lviv Conservatory.[2]
Ní ọdún 1919 ó kọ orin àkọ́kọ́ rẹ̀,– the Liturgy (Літургію), èyí tí ó ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní St. George's Cathedral ní ìlú Lviv.[3]
Ní ọdún 1921, ó kékọ̀ọ́ pẹ̀lú Guido Adler ní University of Vienna àti Joseph Marx ní University of Music and Performing Arts Vienna, tí ó sì kékọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1923.[3]
Ní ọdún 1925 ó fẹ́ Robert Lisovskyi, ó sì rin ìrìn àjò pèlú rẹ̀ lọ sí Berlin, wọ́n jọ gbé pọ̀ láti ọdún 1927 wọ 1930, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ pèlú Arnold Schoenberg àti Franz Schreker.[2] Lásìkò yìí, ní ọdún 1927 ni ó bí ọmọbìnrin rẹ̀, tí ń ṣe Zoya (Зоя) was born.[4]
Ní ọdún 1930, ó lọ sí ìlú Prague ní Czechoslovakia, láti lọ kékọ̀ọ́ pèlú Zdeněk Nejedlý ní Charles University, àti Otakar Šín ní Prague Conservatory. Ó tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ orin sílẹ̀ pẹ̀lú Vítězslav Novák ní ilé-ìwé orin náà. Ní ọdún 1933, ó kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù Ó gboyè gíga nínú ẹ̀kọ́ orin ní ọdún 1934 ní Ukrainian Free University, ó sì di obìnrin àkọ́kọ́ tó ti ìlú Galicia wá tó gboyè gíga ọ̀hún.[2]
Ó padà sí ìlú Lviv, láti ọdún 1934 títí wọ ìbẹ̀rẹ̀ ogun àgbáyé kejì. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ orin ní Lviv Conservatory, ó sì di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbé Union of Ukrainian Professional Musicians.[3]
Àwọn àtòjọ orin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ Síḿfónì rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Symphony No.. 1, 1937
- Symphony No.. 2a, 1952
- Nọmba Symphony 2b, ẹya keji
- Sinfonietta, ọdun 1956
- Meta Symphonic Sketches, Oṣu Keje 3, Ọdun 1975
- Oriki Symphonic "La Vita"
- Symphony Space, 1972
- Suite fun meji okun orchestras
- Irokuro fun Double Okun Orchestra
Ijó bàléè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ọmọbirin naa pẹlu Awọn Ọwọ Rẹ, Bristol, 1957
- Egba Ọgba
- Vesna (orisun omi; Ballet ọmọ), 1934-1935
- Mavka (Igbo Nymph; Ballet Awọn ọmọde), 1964-1967, Belfast
- Strachopud (The Scarecrow), 1976
Ijó ọ́púrà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Mavka - da lori Orin igbo Lesia Ukrainka (ko pe)
Ijó Ijó ọ́púrà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Tsar Okh tabi Ọkàn Oksana, 1960
- Bìlísì Ọ̀dọ́
- A Ewebe Idite, 1969
Awọn iṣẹ Kórà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Liturgy, ọdun 1919
- Orin Dafidi fun Scheptitsky
- Ṣaaju Ogun
- Triptych
- Lullaby (Ah, ko si ologbo), 1946
Iyẹwu - Awọn irinṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Sonata fun violin ati piano, 1935
- Quartet okun, 1960 - 1970
- Mẹta fun violin, viola ati cello, 1960 - 1970
- Piano Quintet, 1960 - 1970
- Afẹfẹ Mẹta, ọdun 1972
Àwọn isẹ́ dùrù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Awọn iyatọ lori akori Ti Ukarain, 1932
- Irokuro. Piano Suite pẹlu Awọn akori Ti Ukarain, 1940
- Impromptu, ọdun 1962
- Grotesque, ọdun 1964
- Mountain Suite, 1966-1968
- Ayika ti Awọn nkan fun Awọn ọmọde, 1936–1946
- Ukrainian Keresimesi carols ati Shtjedrivka
- Irohin ti o dara
- Keresimesi pẹlu Harlequin, 1971
Oriṣiriṣi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Okan, fun ohun ati onilu
- Lorelei, itan ti harmonium ati piano, 1919. Ọrọ nipasẹ Lesia Ukrainka
- Oṣu Karun ọdun 1912
- Awọn akori ti awọn orin eniyan
- Ominira Square, fun duru
- Orin Lemky fun ohun ati awọn gbolohun ọrọ
Ita ìjápọ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ukrainian Art Song Project – Stefania Turkewich
- Stefania Turkewich: Galician I | Awọn orin Aworan naa
- Orin ati Memorial Museum
- "Ọba Oh" tabi Ọkàn ti Oksana
- Fiimu nipa Stefania Turkewich
- Afihan agbaye ti Stefania Turkewich's First Symphony
- Meta Symphonic afọwọya - World Ijoba
- Ere ti a ṣe igbẹhin si ayẹyẹ ọdun 120 ti ibimọ Stefania Turkewich
- Afihan. Stefania Turkewich-Lukiyanovich "Okan Oksana" opera.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ukrainian Art Song Project – Stefania Turkewich". Archived from the original on 2016-03-22.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 Павлишин, Степанія Стефанівна. Перша українська композиторка: Стефанія Туркевич-Лісовська-Лукіянович, БаК, Lviv 2004.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Роман Кравець. "Українці в Сполученому Королівстві". Інтернет-енциклопедія. Archived from the original on 2017-04-27. Retrieved 2018-08-28.
- ↑ "Зоя Робертівна Лісовська-Нижанківська, the Encyclopedia of Modern Ukraine" (in ukrainian). Retrieved 2018-12-17.